Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpèsè Ohun Amáyédẹrùn: Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Pe Fún Ìkúnlọ́wọ́ Àwọn Ilé Iṣẹ́ Aládàáni

0 115

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti rọ àwọn ilé-iṣẹ́ aládàáni láti máa kún ìjọba lọ́wọ̀ lórí iṣẹ́ ìdàgbàsókè àwùjọ àti ìgbáyégbádùn ará ìlú.

Alága ìjọba Ìbílẹ̀ Ìlà-Oòrun Ìbàràpá Olugbenga Abiodun Ọbalọwọ ló sọ̀rọ̀ náà lórúkọ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé
lásìkò ti wọn n ṣi àwọn kàngádẹ̀rọ mẹ́rin tí ilé-iṣẹ́ Guiness Plc gbẹ́ sí ìjọba ìbílẹ̀ Ìlà-Oòrun Ìbàràpá.

Mẹ́ta nínú àwọn kàngádẹ̀rọ ọ̀hún ni wọ́n gbẹ́ sí àgbègbè Ìṣaba àti Eruwa tuntun (New Eruwa) ní ìlù Èrùwà, tí ọ̀kan yòókù sì wà ní ìgboro ìlú Làǹlátẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú ọ̀wọ́n gógó omi tí àwọn olùgbé agbègbè náà ti kojú.


Ìwádìí Akọ̀ròyìn Ilé Akéde Naijiria fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pe, àwọn èèyàn agbègbè Ìṣaba ti wà nínú ìpọ́njú omi tó mọ́ gaara fún ọjọ pípẹ́ látàrí bí àwọn kànga tí wọ́n gbìyànjú láti gbẹ́ kò ṣe kan omi, eléyìí tó mú kí àwọn èèyàn náà fi tìlù-tìfọn pàdé àwọn adarí ilé-iṣẹ́ Guiness Plc tó ṣe àṣeyọrí yìí lọ́jọ́ tí wọ́n ṣí omi náà fún pípọn.

Olùgbé agbègbè ọ̀hun kan, Abilékọ Ọdúnọlá Hassan nígba tó n fi ìdùnnú rẹ̀ hàn ṣàlàyé pé “ládùúgbò yìí, ìyá omi ń jẹ́ wá gan-an, àgàgà lásìkò ẹ̀ẹ̀rùn báyìí, àwọn ọkọ wa gan-an kì í ṣiṣẹ́ dàbí alárà, omi ni wọ́n máa ń wa káàkiri ni gbogbo àsìkò ẹẹrun”.

Nígbà tó n fi ìdùnnú rẹ̀ hàn sí ẹ̀bùn omi naa, Alága Ìjọba Ìbílẹ̀ Ìlà-Oòrun Ìbàràpá Olugbenga Abiodun Ọbalọwọ sọ gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé:
“Inú wa dùn pé nígbà tí ẹ n ṣe ìwádìí lórí àwọn ibi tí ẹ fẹ́ gbẹ́ àwọn kàngádẹ̀rọ wọ̀nyí sí, àwọn agbègbè tí wọ́n ti nílò omi gan-an lẹ mú, ẹ kò fi òṣèlú ṣe é rárá.


Àwọn àdúgbò tó nílò omi pọ̀ gan-an nílùú Èrùwà àti Làǹátẹ̀, a tún nílò irú omi báyìí láwọn àdúgbò mí-ìn náà ní ìjọba ìbílẹ̀ yìí. A si ṣetan láti mójútó wọn dáadáa kí wọ́n ma baà ṣe bàjẹ́.”

Ṣáájú ni Ọ̀gbẹ́ni John Monsinga, tí i ṣe Alákòóso àgbà ilé-iṣẹ́ Guiness ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà Ṣeyi Mákindé fún bó ṣe fi ààyè gbà wọ́n láti gbẹ́ àwọn kàngádẹ̀rọ náà.

Bákan náà ló rọ àwọn olùgbé àwọn agbègbè tí wọ́n pèsè omi náà sí láti mójú tó wọn dáadáa nítorí èèyàn tí kò dín ní mílíọ̀nù mọ́kànlá ni omi náà yóò ṣe ànfààní fún.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button