Ìpàdé Àpérò Lórí Ètò Ọrọ̀ Ajé Ti Ọdún 2023 Tí Ìrètí Wà Pé Yóò Wáyé Ní Ìpínlẹ̀ Gombe Ti Sún Síwájú
Ìjọba Ìpínlẹ̀ Gombe ti kéde sísún síwájú ìpàdé àpérò ètò ọrọ̀ ajé ti ọdún 2023 èyí tí ìrètí wà pé yóò wáyé ní ọjọ́ kẹrìndínlógún sí ọjọ́ kẹtàdínlógún osù kọkànlá, ọdún yìí.
Alága ìgbìmọ̀ ètò náà tí ó tún jẹ́ igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Gombe, Ọ̀mọ̀wé Menassah Daniel Jatau ni ó kéde ìsún-síwájú nínú ìwé tí ó fi sọwọ́ sí àwọn akọ̀ròyìn
Ìgbìmọ̀ sàlàyé síwájú pé àpérò náà yóò padà wáyé ní ọjọ́rú, ọjọ́ keje sí Ọjọ́bọ̀ ọjọ́ kẹjọ osù kejì ọdún 2024. Ó wá dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọba ìpínlẹ Gombe fún àtìlẹyìn rẹ̀ lórí ètò náà, ó sì fi àrídájú hàn pé, ètò náà yóò so èso rere.