Take a fresh look at your lifestyle.

Gbajú-gbajà Òsèré Ọmọ Orílẹ̀-èdè Améríkà, Mathew Perry Dágbére Fún Ayé Ní Ẹni Ọdún Mẹ́rìnléláàdọ́ọ́ta

0 222

Ìlu-mọ̀ọ́ká òsèré ọmọ Orílẹ̀-èdè Amẹrika, Mathew Perry papòdà ní ẹni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́ọ́ta

Àwọn agbófinró fi tó àwọn akọ̀ròyìn létí pé, wọ́n se àwárí òkú rẹ̀ ní ilé ìgbé rẹ̀ tí ó wà ní Los Angeles

Àwọn oníròyìn tí ó kọ́kọ́ se ìfiléde ikú rẹ̀ sàlàyé pé, wọ́n bá a nínú ilé ìgbé rẹ̀ lẹ́ni tí ẹ̀mí ti bọ́ lára rẹ̀, tí akitiyan àwọn dókítà kò sì le è ra ẹ̀mí rẹ̀ padà.

Ó jẹ́ gbajú-gbajà eléré, èyí tí ìròyìn fi yéwa pé àádọ́ta mílíọ̀nù lé díẹ̀ ènìyàn ni ó wo eré tí ó se gbẹ̀yìn lórí ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán, èyí tí kò sí akẹgbẹ́ rẹ̀ ní àsìkò tí a wà yìí.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.

button