Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Bọ́lá Ahmed Tinubú ti gbósùbà ràbàndẹ̀ fún Ọọ̀ni ti ilé-ifẹ̀ (Oba Adeyeye Ogunwusi) látàrí bí ó se ń gbé àṣà àti ìṣe ilẹ̀ Yorùbá lárugẹ.
Ààrẹ Tinubu wí pé, láti ìgbà Kábíyèsí ti gorí ìtẹ́ baba rẹ̀, ìṣàkóso rẹ̀ ti lé ìdàrúdàpọ̀ lọ, ó ti wá ọ̀nà àbáyo sí àwọn wàhálà, ìlú sí ń tẹ̀ síwájú, gbogbo nǹkan ti àwọn ènìyàn ń fẹ́ nílé àti lókè òkun ni ó gbìyànjú láti ṣe.
Ìgbóríyìn yí wá bí ààrẹ se ń yayọ̀ pẹ̀lú Ọọ̀ni ti ilé-ifẹ̀ àti alága àpapọ̀ àjọ National Council of Traditional Rulers of Nigeria, NCTRN, ni ẹni ọdún mọ́kàndínláàdọta.
Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni kú oríire ààrẹ Tinubú sí Oọ̀ni ti ilé ifẹ̀, Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọba alayé náà fún ṣíṣe atìlẹ́yìn fún ìjọba rẹ̀ àti bí ó se kó gbogbo àwọn lọ́balọ́ba yọ́kù káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè yìí mọ́ra pẹ̀lú ìfẹ́.
Ó wá gbàdúrà fún Ọba alayé náà fún ẹ̀mí gígùn àti àlàáfíà pípé.
Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, (Ọjájá II) ni wọ́n bi ni ọjọ́ kẹtàdínlógún, ọdún 1974. Ó jẹ́ ọba kọkànléláàdọ̀ta, o sì jẹ́ Ọba tó wà lórí ìtẹ báyìí. Ọba alayé ilé ifẹ̀ àti ilẹ̀ Yoruba ní àpapọ̀ ló jẹ́.
Ọba Ogunwusi gun orí ìtẹ́ baba rẹ̀ ní ọdún 2015 ni ìgbà tí Ọba Okunade Sijuwade wàjà, òun ni ó jẹ́ Àádọ́ta Ọọ̀ni ti ilé-ifẹ̀.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply