Take a fresh look at your lifestyle.

Omíyalé gbẹ̀mí ènìyàn mẹ́tàdín-lógún ní Àringbùngbùn DR Congo

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 108

Ilẹ̀ jíjìn ti gbẹ̀mí àwọn ènìyàn mẹ́tàdín-lógún ní orílẹ̀-èdè Congo.

Ajalu naa ṣẹlẹ ni alẹ ọjọ Aiku lẹgbẹ eti omi Congo, ní Àringbùngbùn ilu Lisala, olu ilu agbegbe Mongala.

Awọn obinrin meje, ọkunrin meje, ati awọn ọmọde mẹta ti ko ju ọdun marun lọ padanu ẹmi wọn.

Wọn sin wọn ni ọjọ kan naa nitori pe ko si aaye ti wọn le ko wọn si ni ile ti wọn n gbe oku si lagbegbe wọn, ní Lisala, oṣiṣẹ Désiré Koyo sọ bayii.

Ojo arọrọda fun ọpọlọpọ ọjọ yii lo fa iku naa.Awọn ti o ṣoju wọn sọ pe awọn ọpọlọpọ ile to wa leti omi naa ni omi naa mù doke ti awọn olugbe si n ja fitafita lati gba awọn eniyan silẹ ninu erupẹ.

Gomina Mongala, César Limbaya, ba ẹbi awọn to padanu ẹmi wọn kẹdun.

O wa kede ikẹdun wọn fun ọjọ mẹta, leyi ti yoo bẹrẹ ni ọjọ Aje, lasiko ti yoo ta Asia soke.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.