Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé ẹjọ́ da ẹ̀sùn APC sí Gómìnà Lawal ti Zamfara nù

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 90

Ilé ẹjọ́ tí ń yanjú aweyewuye tó bá wáyé lórí ìbò gómìnà, ti ìpínlẹ̀ Zamfara ti da ẹ̀sùn tí  ẹgbẹ́ All Progressive Conress (APC) àti olùdíje ipò gómìnà rẹ̀, Bello Matawalle fi kan gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Dauda Lawal nù.

Alaga Ilé ẹjọ́ tí ń yanjú aweyewuye tó bá wáyé lórí ìbò naa, Adajọ Cordelia Ogadi, ti o dari awọn ọmọ ẹgbẹ meji toku, da ẹsun naa nu nitori pe ko si ootọ kankan lati dimu nibẹ ti olupẹjọ ko si ni ẹri si ẹjọ rẹ gẹgẹ bi ofin ṣe lana silẹ.

Ilé ẹjọ́ naa sọ pe olupẹjọ ko ri ẹri pese fun aiṣe deedee ti o ni o waye lasiko ibo naa ti wọn si ni ki o san iye owo ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ta ẹgbẹrun fun awọn mẹta ti wọn fẹsun kan.

Awọn Oludahun si ẹsun naa ni; Lawal, ẹgbẹ oṣelu rẹ, Peoples’ Democratic Party (PDP) ati igbimọ olominira to n riri eto idibo lorile-ede (INEC).

Leave A Reply

Your email address will not be published.