Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Fintiri tẹnumọ́ ìpinnu láti ṣàtúnṣe ìpínlẹ̀ Adamawa

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 76

Gómìnà ìpínlẹ̀ Adamawa, Amadu Fintiri tún ń fìdí ojúṣe ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, èyí tí ó jẹ́ àti fa ojú àwọn olùdókòwò mọ́ra, kí ó sì ṣàgbéga ìpínlẹ̀ náà àti ìgbélárugẹ oríṣiríṣi Àṣà tí ó mú ìlú náà yàtọ̀ sí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nípasẹ̀ Ètò Ìpinnu Mọ́kanlá rẹ̀.

Gomina fi idi eyi mulẹ nipasẹ Ọga agba fun awọn oṣiṣẹ,Edgar Amos lasiko ifọrọjomitoro ọrọ pẹlu awọn oniroyin ni ile ijọba, ni Yola ni ipari ọsẹ.

O sọ pe ojuṣe oun ni lati sin awọn eniyan daradara. Ilu naa yoo si ni iyi ati ifọkansi.

Eto ipinnu mọkanla naa ni aabo ẹmi ati Dukia, Ẹkọ ati idagbasoke ironilagbara, iṣododo ati ikunju osunwọn.

Awọn to ku ni ipese omi, idagbasoke ọgbin atiaabo ounjẹ, itọju ilera ati  iṣẹ ọmọniyan, idagbasoke ọdọ ati awọn obinrin, katakara ati ile-iṣẹ. Atunṣe iṣẹ ijọba, agbegbe ati iyipada oju ọjọ.

Leave A Reply

Your email address will not be published.