Take a fresh look at your lifestyle.

Edo 2024: Àwọn Ọba buwọ́lu Imuse, Alága APC, Fún Gómìnà

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 73

Àwọn Ọba ní Àringbùngbùn Edo, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Enijies, ti fòhùntẹ̀ lu èròńgbà alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Ajagun fẹ̀yìntì David Imuse, láti jẹ gómìnà nínú ìdìbò 2024 ti ń bọ̀ lọ́nà yìí.

Àwọn Ọba naa ti idi atilẹyin wọn mulẹ ni ọjọ Aiku nigba ti wọn n gbalejo oludije ipo gomina naa ati iyawo rẹ ni Aafin Abumere,  Onojie ti ilu Ekpoma, nibi ti gbogbo wọn ti pejọ.
Imuse, ti awọn alatilẹyin ati awọn oloṣelu to nifẹẹ rẹ naa darapọ mọ, wa jẹ ki ọba naa mọ erongba oun lati ṣakoso ipinlẹ naa ni ọdun 2024 ti o n bọ.

Alaga APC wa sọ pe kii ṣe pe nitori oun wa lati Aringbungbun Edo ni oun ṣe  fẹ ṣe gomina, bi ko ṣe pe oun ni ọgbọn, oun kunju osunwọn, ti oun si kapa lati ṣee.

O sọ pe nitori pe oun mọ ojuṣe gomina, oun yoo jẹ gomina ti o dara, ti oun ba ri tikẹẹti ẹgbẹ oun gba ti oun si yege ninu idibo naa..
Imuse, ti o kawe jade ni ile ẹkọ giga fafiti Benin gẹgẹ bii oniṣegun, ṣiṣẹ ni ile iṣẹ ologun Naijiria ki o to fabọ si karakata tara rẹ ati oṣelu, wa n fi da awọn ọba naa loju pe oun yoo fakọ yọ.

Leave A Reply

Your email address will not be published.