Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn akẹkọ̀ọ́ jáde pè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ìjọba Nàìjíríà lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 74

Alága ìgbìmọ̀, Ẹgbẹ́ Àwọn akẹkọ̀ọ́ jáde ti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Igbobi, Bode Thorps ti pè fún àtúnbọ̀ fisọ́kàn nípa ṣíṣe ẹ̀kọ́ lálábọ́ọ́dé fún àwọn ọmọ Nàìjíríà nípasẹ̀  fífọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Àwọn akẹkọ̀ọ́ jáde ti ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ilé-ìwé gíga jákèjádò orílẹ̀-èdè.

Ọgbeni Thorps ti o n ba  Voice of Nigeria sọrọ ni ilu Eko lasiko ipade gbogbogboo ọlọdọọdun 2023 ẹgbẹ naa sọ pe Àwọn akẹkọ̀ọ́ jáde ile-ẹkọ giga  Igbobi ti gbogbo eniyan mọ si ICOBA ko yee ṣe daradara fun ile iwe naa, paapaa julọ lori idagbasoke Amayedẹrun ati ni riri daju pe awọn olukọ gbowo to jọju.

O wa rọ àwọn akẹkọ̀ọ́ jáde ti awọn ile iwe miiran naa ni Naijiria, lati maa pese iranlọwọ fun awọn ile iwe ti wọn ti jade lati jẹ ki ẹkọ tunbọ rọju ni orilẹ-ede.

Ikan lara awọn ọmọ ẹgbẹ ICOBA, Abayomi Alabi, wa rọ ijọba lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn akẹkọ̀ọ́ jáde àwọn ilé-ẹ̀kọ́ ni Naijiria lati nawo lori ẹkọ fun igbelarugẹ ẹkọ.

Leave A Reply

Your email address will not be published.