Àlùfáà ìjọ kan ní ìlú Eko, Wòlíì Adewale Martins ti rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà pàápàá jùlọ àwọn adarí ẹ̀sin láti máa ṣe ìtọrẹ àánú fún àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́.
Gẹgẹ bi Alufaa naa ṣe sọ, ipọnju ti n koju awọn ọmọ Naijiria bayii fẹ amojuto ni kiakia, ti o si n rọ ijọba ati awọn adari ni gbogbo ipele lati wa nnkan ṣe lori rẹ.
O n sọ eyi lasiko ayẹyẹ ogoji ọdun ati ayẹyẹ ọdun kẹẹdọgbọn ti o di Alufaa, ní ilu Eko.
Idunnu ṣubu layọ Alufaa naa ti o ṣayẹyẹ naa pẹlu awọn ẹlẹgbẹ rẹ mẹrin: Monsignors Edmond Babashay Akpala, Jerome Gbenga Odunkan, Michael Femi Akintolu ati Alphonsus Iweanya Ania.
Alufaa wa n dupẹ lọwọ ọlọrun ti o ṣọ lati igba naa titi di ọjọ toni, o tun wa gba awọn Alufaa to ku nimọran lati kun fun adura ki wọn o si gbe iyi Woli larugẹ.