Take a fresh look at your lifestyle.

Adarí ọ̀dọ́ PDP Bayelsa, olùránlọ́wọ́ pàtàkì fún gómìnà, Diri fi ẹgbẹ́ sílẹ̀

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 92

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú People’s Democratic Party (PDP) ní ìpínlẹ̀ Bayelsa, pẹ̀lú àdarí àwọn ọ̀dọ́ ẹgbẹ́, Nunieh Odede, ti fi ẹgbẹ́ sílẹ̀ bí ìbò ọjọ́ kọkànlá, oṣù kọkànlá ṣe ń bọ̀ ní ìpínlẹ̀.

Odede ati awọn to ku yi ọkan wọn pada kuro lọdọ gomina Douye Diri si oludije ipo gomina fun ẹgbẹ All Progressives Congress (APC), Oloye Timipre Sylva.

Ninu lẹta kan ti wọn fọwọ kọ ti wọn ri ni ọjọ Aje, ni Yenagoa, olu ilu, Odede kede ikọwe fiṣẹ silẹ rẹ kuro ni PDP ti awọn oluranlọwọ pataki fun gomina naa si fi ipo wọn silẹ lati ṣe ipolongo fun Sylva.

Alaye kan ti oludamọran pataki fun Sylva lori eto ibaraenisọrọ ati ipolongo Julius Bokoru, buwọlu fidiẹ mulẹ pe  Odede ṣe ipade pẹlu oludije fun ipo gomina ẹgbẹ APC.

Ninu Alaye naa  Sylva wa gboriyin fun igboya Odede ati awọn toku to kuro, ti wọn duro fun idagbasoke ati ilọsiwaju ipinlẹ yatọ si imọtaraẹni nikan.

Leave A Reply

Your email address will not be published.