Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu yan Jamila Bio, Ọlawande ní Mínísítà Fún àwọn ọ̀dọ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 70

Ààrẹ Nàìjíríà, Bọla Ahmed Tinubu ti buwọ́lu yíyan Dókítà Jamila Bio Ibrahim fún Míníst fún àwọn ọ̀dọ́, títí di ìfìdímúlẹ̀ rẹ̀ láti ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Oludamọran pataki fun aarẹ lori eto ibaraẹnisọrọ ati ipolongo, Ajuri Ngelale fi idi eyi mulẹ ninu alaye kan ti o buwọlu.

Aarẹ tun buwọlu yiyan Ọgbeni Ayọdele Ọlawande si ipo Minisita ipinlẹ fun awọn ọdọ, títí di ìfìdímúlẹ̀ rẹ̀ láti ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Dokita Jamila Bio Ibrahim jẹ onimọ iṣegun ti o si jẹ aarẹ igbimọ idagbasoke awọn ọdọbinrin (PYWF), ki wọn to yan si ipo Minisita yii.

O tun figba kan jẹ oluranlọwọ pataki fun gomina ipinlẹ Kwara fun Eto erongba idagbasoke ibiafẹde (SDGs).

Ọgbẹni Ayọdele Ọlawande jẹ onimọ idagbasoke agbegbe ati adari awọn ọdọ ninu iṣakoso ẹgbẹ oṣelu All Progressives’ Congress (APC).

Leave A Reply

Your email address will not be published.