Olórí Ológun àti orílẹ̀-èdè Mali ti sọ pé àwọn ti fagilé ayẹyẹ àlàkalẹ̀ fún ayẹyẹ ọdún òmìnira ti wọ́n fẹ́ se tẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ kejìlélọ́gún oṣù Kẹ̀sán ọdún yìí. Wọ́n sọ èyí nígbà ti ìgbìmọ̀ àwọn Mínísítà ti ṣe pàdé.
Ọdún tó kọjá, Olórí ológun àti olórí orílẹ̀-èdè Guinea báwon se ajoyọ̀ òmìnira ọdún Méjìlélọ́gọ̀ta.
Ni ibi ìpàdé àwọn Mínísítà, olórí Ológun àti olórí orílẹ̀-èdè Mali, pàṣẹ pé owó tí wọ́n fẹ fi se pọ̀pọ̀ sìnsìn ayẹyẹ òmìnira ni kí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún itọju àwọn ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkọ̀lù débá ní àìpẹ́ yii.
Ní ọjọ́ Ìsẹ́gun, ológun Tuareg àti àwọn esinòkọkú kọlu àwọn ọmọ ológun ní ìlú
Bourem ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ológun sọ pé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn dáa padà.
Ìròyìn ti ikọ̀ méjèèjì ń sọ kò yé àwọn ènìyàn sùgbọ́n ikọ̀ méjèèjì ni wọ́n ti ri ọ̀pọ̀ ènìyàn tó kù.
Ìkọ̀lù sí ọkọ̀ ojú omi tó n ko àwọn ènìyàn lọ ní ọ̀ṣẹ̀ tó kọjá ní etídò Niger ló ti jẹ́ ki ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìmọ̀kan gbẹ̀mī mì . Wọn sì ti di ẹ̀sùn Ìkọ̀lù náà ru àwọn esinòkọkú
Èyí ń ṣẹlẹ̀ lẹyìn ti àjọ apẹ̀tù síjà fún aláàfíà kó jọba ti UN ń kó ọmọ ogun wọn padà lọ sí ibi ti wọ́n ti wá.
Orilẹ-ede Mali bọ sínú wàhálà ní ọdún 2012 léyìn ti àwọn alájàngbilà àti ẹsinòkọkú se Ìkọ̀lù ni agbègbè Àríwá.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san