Ọmọ Nàìjíríà to n se Fíìmù, Deji Pillot, ti gbósùbà rabande fún ilé ìṣẹ́ Netflix àti Amazon Prime fún gbígbe ayika tó dẹrùn kalẹ̀ fún ilé iṣẹ fíìmù láti sọ ìtàn wọn tó sọrọ nípa ọpọlọpọ àṣà àti ìṣẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà to rẹwa.
Oludari Deji Media Ltd sọ èyí ni ọjọ́ Ọjọ́bọ̀ nigba ti News Agency of Nigeria n fi ọ̀rọ̀ wa lẹnu wò ni ilu Èkó.
Bi o se sọ, pẹlu Iranlọwọ àwọn wọ̀nyí, ilé iṣẹ́ fíìmù ni Nàìjíríà ti ráyè fẹsẹ̀ tilẹ̀ láti la àgbáyé já, ó ràn wọn lọ́wọ́ láti sí ilẹkùn lati ri wọn tàbí gbọ́ wọn káàkiri gbogbo ayé.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san