Take a fresh look at your lifestyle.

Mínísítà Ètò Ìròyìn Se Ìlérí Àtìlẹ́yìn Fún Àjọ Public Complaints Commission

0 83

 

Mínísítà fún ètò Ìròyìn, Mohammed Idris ti sọ pé Mínísírì òun yóò ṣe àtìlẹyìn fún àjọ Public Complaints Commission nínú iṣẹ́ rẹ̀ pàápàá jù nínú ìpẹ̀tù sí ááwọ̀.

Mínísítà sọ eyi nígbà ti àwọn adarí àjọ náà ló kíì ní Àbùjá.
Ọ̀gbẹ́ni Idris sọ pé iṣẹ àjọ náà ni wọn kò fi sí etí ìgbó àwọn ènìyàn dáradára, ó wá pinnu láti ìsínsìnyí lọ láti ran wọ́n lọ́wọ́, pé gbogbo ìpolongo tó yẹ ni àwọn yóò ṣe láti je ki ọpọlọpọ ọmọ Nàìjíríà jẹ ànfààní tó wà nínú Iṣẹ́ wọn, láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn ní ìgbẹkẹ̀lé nínú akitiyan ìjọba.

Komisọ́na pátápátá fún àjọ Public Complaints Commission, Abimbola Ayo-Yusuf sọ pé wọn rí ẹ̀sùn tó dín díẹ̀ ní Ọ̀dúnńún ẹgbẹ̀rún gbà láti ọjọ kínní oṣù kẹfà, ọdún 2021 sí ọjọ́ kínní oṣù Keje, ọdún 2923, wọ́n sì ti bá wọn yanjú ẹsùn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ìgbà ó dín ni ọgbọ̀n ẹgbẹ̀rún.

Komisọ́na àgbà pátápátá ajo naa bere fún ìwé afọwọsi lati leè túbọ̀ ró iṣẹ́ wọn lágbára àti àwọn nǹkan míràn, Mínísítà
sì se ìlérí pé gbogbo rẹ̀ ni wọn yóò gbéyẹ̀wò.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.