Take a fresh look at your lifestyle.

Ó Ṣeéṣe Ká Fi Kún Àsìkò Akọ́ni-mọ̀ọ́gbá Àwọn Obìnrin – Àjọ NFF

0 97

Àjọ NFF ti kàńpá fún ìgbìmọ̀ tó mójú tó eré bọ́ọ̀lù láti bá akọ́ni-mọ̀ọ́gbáà awọn obìnrin, Randy Waldrum sọ̀rọ̀ bóyá kí ó tẹ síwájú gẹ́gẹ́ bí adarí àwọn agbábọ́ọ̀lù obìnrin ilẹ̀ Nàìjíríà.

Ọ̀gbẹ́ni Waldrum tu ọkọ̀ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù

obìnrin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ti gbadé fún ìgbà mẹ́sàn án ní ilẹ̀ Áfíríkà lọ sí ipele ẹlẹ́ni mẹ́ẹ̀dógún ní ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ti àwọn obìnrin tó wáyé ní ilẹ̀ Australia àti  New Zealand.

Ikọ̀ Super Falcons padà wálé lẹyìn tí ikọ̀ ti England gbo ewúro si ojú wọn ní abala golí wòó kí n gba sí ọ látàrí pé wọn kò rí won nà titi àkókò ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ fi parí.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.