Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Kenya William Ruto yóò ṣé ayẹyẹ ọdún kàn lórí àléfáà ní ọjọ́ Ọ̀jọ́bọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ kàrún nínú ìtàn orílẹ̀-èdè náà tí àwọn amòye ṣàpèjúwe rẹ̀ bí èyí tó ní ipenija.
Ó ṣé ìlérí tó pọ̀ làkókò ìpolongo ìbò rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ látí orí ọrọ̀ ajé, ìrànwọ́ owó fún àwọn ọlọja kékèké àti àwọn mìíràn sùgbón ‘omi pọ̀ jù ọkà lọ́.’