Ààrẹ orílẹ̀-èdè Zimbabwe Emmerson Mnangagwa ní àwọn aráàlú tí fí ẹsùn kàn bó ṣé yán ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkàn nínú àwọn Mínísítà títún lẹyìn ìdìbò tó ní àríyànjiyàn nínú ní Oṣù tó kọjá.
Ọ̀gbẹ́ni Mnangagwa ní ọjọ́ Ajé pé ọmọ rẹ̀, David Kudakwashe, gẹ́gẹ́ bí Ìgbákejì Mínísítà ìnáwó.
Tún kà nípa:Emmerson Mnangagwa Gbá ìwé Àṣẹ Sáà Kejì Gẹ́gẹ́ Bí Ààrẹ Zimbabwe
Ó tún yán ọmọ ẹbí rẹ̀, Tongai Mnangagwa, gẹ́gẹ́ bí Ìgbákejì Mínísítà ìrìn-àjò, àwọn òníròyìn àgbègbè náà sọ́.
Agbẹnusọ àwọn àlátákò Citizens Coalition for Change (CCC) Fadzayi Mahere àti àwọn aráàlú kàn bú ẹnú àtẹ lú áìṣédéédé náà.
Kó tíì sí èsi kánkan látí ọdọ ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí Ààrẹ lórí ẹsùn náà. Sibẹsibẹ àwọn àlàtìlẹ́yìn tí Ọ̀gbẹ́ni Mnangagwa sọ pé ọmọ rẹ̀ lẹ́tọ́ sí ipò náà.