Àgbábọ́ọ̀lù Borussia Dortmund tẹ́lẹ̀ Anthony Modeste tí dárapọ̀ mọ́ Al Ahly lórí àdéhùn ọdún kán, lẹyìn ọdún kàn tó dárapọ̀ mọ́ Borussia Dortmund tí German.
Àdéhùn Al Ahly pẹ̀lú Modeste ọmọ France lé tèsíwájú fún ọdún kàn mìíràn ní ìbámu sí àdéhùn láàrín wọ́n.
Ó lé bẹ̀rẹ̀ sí ṣójú ìkọ náà látí ọjọ́ Ẹtì tó nbọ́, nígbàtí Al Ahly yóò kojú USM Alger tí Algeria ní ìdíje Super Cup Áfíríkà, tí yóò wáyé ní Saudi Arabia.
Líìgì Egypt yóò bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ kẹta ìdíje náà.