Àwọn ẹgbẹ́ Oníṣègùn nípa ọ̀rọ̀ ẹyìn ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí sún èròngbà ìyanṣẹ́lódì olósù méta wọn síwaju.
Mínísítà fún ètò ìlera Muhammad pate sọ wí pé ìyanṣẹ́lódì náà wà fún àtúnse láàrín ẹgbẹ́ náà àti ìjọba.
Níbi ìpàdé tí o wáyé ní ìpínlẹ̀ Kano ni ọ̀rọ̀ náà ti jẹ yọ
Muhammad sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn Oníṣègùn Òyìnbó se n fí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sílẹ̀ láti lò ṣiṣẹ́ lókè òkun
O wà be ìjọba àpapọ̀ láti wá ǹkan ṣe sí ní kíákíá, nípa pípèse agbegbe to dára àti àwọn ọ̀rọ̀ ìwúrí eyi ti yóò mú kí ìdàgbàsókè dé bá ètò ìlera.
Muhammad pe ìjọba ìbílẹ̀ to fí dé ìjọba àpapọ̀ láti rí wí pé wọ́n pèsè àwọn òun tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́