Abẹ́rẹ́ àjẹsára: Ó ṣeéṣe kí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Jẹ́ Gbọ̀gàn Ibi Tí Wọn Yóò Ti Ma Pèsè Abẹ́rẹ́ Àjẹsára: Mohammed Pate.
Mínísítà ti o n ṣàkóso MIN ọ̀mọ̀wé Muhammad pate ti sọ wí pé o dá òun lójú wí pé Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò jẹ gbọgán ibi ti wọn yóò ti ma pase àbẹ́rẹ́ àjẹsára fún Orílẹ̀-èdè Áfíríkà láìpé
Pate sọ èyí di mímọ̀ nígbà tí o ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ní ìlú Abuja, nípa ìrètí àtúnse fún ètò ìlera ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Mínísítà tẹnumọ bi a se pọ tó ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn ẹbùn, ìmọ̀ àti àwọn òhun ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí yóò ṣe àtìlẹ́yìn fún ìpèsè àbẹ́rẹ́ àjẹsára náà.
Ó ni ṣùgbọ́n àwọn Ìpèníjà kánkan wa ti a gbọdọ borí ki àwọn ǹkán wọnyi ba lè bọ sí Ṣíṣe.
Ó pè fún ìbáṣepọ̀ tó dàn mọ́rán láàrin ìjọba àpapọ̀ àti àwọn ilé iṣé alàádáni ti yóò mú kí àtìlẹ́yìn pípé wa ki pipese abẹ́rẹ́ àjẹsára náà bá di kíákíá.