Ó kéré ju ẹ̀nìyàn márùndín-lógójì ti pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tí “ ẹ̀rọ abúgbàmù “ dún ní ọjà kan tí ó máa ń kún ní olú ìlú Sudan, aláànú ìtọ́jú.
Médecins Sans Frontières (MSF) ṣapejuwe rẹ bii “o burujai”, ti wọn si n sọ o ju ọgọta eniyan lọ ti o fara pa nibi ikọlu naa.
Awọn oluranlọwọ agbegbe sọ pe ọkọ ofurufu ologun ya bo ọja Qouro ní Gusu Khartoum ní ọjọ Aiku.
Awọn ologun ti n jowu ara wọn ti n ja lati oṣu Igbe.
Ni ọjọ Aiku, adari pajawiri MSF Marie Burton sọ pe Khartoum “ti wà nínú ogun fún bíi oṣù mẹ́fà”.
MSF ṣalaye pe “ohun ija abugbamu” ti kọlu ọja naa ti atẹgun to le si n tẹsiwaju ninu “ idaamu airotẹlẹ ọjọ miiran ati ipadanu ẹmi”.