Ilé-iṣẹ́ ti kìíṣe tìjọba, Agbẹnusọ àwọn obìnrin fún gbígba Àjẹsára WAVA, àti àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Àjọ ẹgbẹ́ ọmọ ìlú ti ṣe idanilẹkọ fún àwọn Àjọ ẹgbẹ́ ọmọ ìlú ní Nàìjíríà láti ṣe ìtanijí fún ìfilọ́lẹ̀ Human Papilloma Virus Vaccines HPV fún àwọn ọmọbìnrin Nàìjíríà, ọdún mẹ́sàn án sí ọdún mẹ́rìnlá.
Nibi ifilọlẹ WAVA HPV ni Abuja, Naijiria, Alaga WAVA, Dokita Chizoba Wonodi ṣalaye pataki ajẹsara naa ni kikoju, didinku ati niwo aarun naa san.
Wonodi wa sọ pe ajẹsara HPV wa fun lati dẹkun aarun jẹjẹrẹ ati pe WAVA naa n pe awọn eniyan jọ lati wa atilẹyin fun ajẹsara naa.
Ni tiẹ, Dokita Bassey Okposin ti ile iṣẹ to n mojuto idagbasoke ilera abẹle lorilẹ-ede sọ pe ifilọlẹ ajẹsara naa yoo dena ki awọn ọmọbinrin maa ni aarun HPV.