Ìjọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ wí pé ìpàdé G20 ti yóò mú àwọn adarí Orílẹ̀-èdè káàkiri péjọ ni Orílẹ̀-èdè India jẹ ànfààní nlá fún Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Wọn ní èyí yóò fi hàn wí pé ìjọba Ààrẹ Bọla Tinubu gbà ànfààní náà láyè lai wo ẹ̀yìn,
Nígbà tí ó ń ṣàlàyé fún àwọn oníròyìn ní ọjọ́ ẹtì, olùdámọ̀ràn pàtàkì fún ìjọba àpapọ̀ lórí ọ̀rọ̀ ayélujára láti ọ̀rọ̀ gbogbo, Ajuri Ngelele, ni ìjọba Ààrẹ Tinubu yóò kópa níbi ìpàdé náà pẹ̀lú ẹ̀kọ́ to yẹ kóró.
Ọ̀gbẹ́ni Ngelele ni kókó ìdí tí àwọn yóò ṣe lo síbi ìpàdé náà ni láti lò kọ́ ẹ̀kọ́ nípa káràkátà láti òkè òkun ati bi Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò ṣe má jẹ èrè káàkiri àgbáyé fún ìdàgbàsókè Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.