Mínísítà ètò ọkọ̀ òfurufú pinnu láti lo iṣòdodo fùn ìdàgbàsókè ẹ̀ka náà
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Mínísítà fun ètò ìdàgbàsókè ọkọ̀ òfurufú, Festus Keyamo ti bẹrẹ iṣẹ ni kete ti aarẹ Naijiria Bọla Tinibu bura fun wọn tan ni gbọngan igbalejo aarẹ, ni Abuja, olu ilu Naijiria.
Nigba ti o n sọrọ nile iṣẹ ijọba naa, Festus Keyamo sọ pe, iṣododo, ajọṣiṣẹpọ ati ifẹran ọmọnikeji yoo jẹ ki o ṣe aṣeyọri lori iṣẹ ti aarẹ gbe fun ni ikọ̀ ètò òfurufú.
Keyamo pinnu lati maa ba awọn iṣẹ akanṣe ti Minisita eto ọkọ ofurufu to ṣẹṣẹ kuro, Ṣẹnetọ Hadi Sirika lọ gẹgẹ bi iṣe lati ṣe idagbasoke ni ikọ eto ọkọ ofurufu.
Minisita wa sọ pe ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú labẹ iṣakoso oun yoo ni aṣeyọri to lami, “Mo ko eniyan mora, erongba mi si ni lati tẹ awọn eniyan lọrun,’’ Keyamo sọ bayii.
Nigba ti o n gbẹnusọ fun awọn oludari ati awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ naa, Akọwe agba, Ọgbeni Emmanuel Meribole wa fi idunnu ati iṣetan awọn oṣiṣẹ lati ṣiṣẹ pẹlu Minisita han..