Ìjọba Israeli yóò fọrọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Nàìjíríà láti pèsè Mílíọ́nù iṣẹ́
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ìjọba Israeli ti túnbọ̀ fi ìdí ìpinnu rẹ mulẹ lori fọrọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Nàìjíríà láti pèsè Mílíọ́nù iṣẹ́ lorilẹ-ede
Aṣojú Israeli sí Nàìjíríà, Michael Freeman, sọ eléyìí níbi ìfilọ́lẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta ètò Innovation Fellowship for Aspiring Inventors and Researchers (i-FAIR), ní Abuja, olú-ìlú Nàìjíríà.
(i-FAIR) jẹ́ ètò kan tí ìjọba Israeli gbé kalẹ̀ láti gbé àwọn ọ̀dọ́ olùpèsè,olùṣẹ̀dá àti aṣèwáádí ní Nàìjíríà.
i-FAIR, jẹ́ ètò olóṣù mẹ́fà tí yóò fààyè gba olùkópa láti mú ọgbọ́n wọn wá sí ìmúṣẹ, nípa pípèsè ìmọ̀-ẹ̀rọ àti ohun èlò ẹ̀kọ́, pẹpẹ, ìtọ́sọ́nà,ìmọ̀ràn àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n láti orílẹ̀-èdè Israel àti Nàìjíríà.
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ìfilọ́lẹ̀ náà, Aṣojú Israeli sí Nàìjíríà, Michael Freeman sọ pé ìjọba Israeli ṣàtìlẹyìn, tí wọn sì fọwọ́sí èròńgbà ààrẹ Tinubu láti ṣàtúnṣe àti láti túnbọ̀ fìdí ọrọ̀-Ajé Nàìjíríà múlẹ̀ nípasẹ̀ pípèsè Mílíọ́nù iṣẹ́ lorilẹ-ede.