Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinúbú Se Ìpàdé Pọ̀ Pẹ̀lú Gómìnà Ìpínlẹ̀ Plateau

0 119

 

Ààrẹ Tinúbú ní ọjọ́ Ọjọ́rú se ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú Gómìnà Plateau, ọ̀gbẹ́ni Caleb Mutfwang ní gbọ̀ngàn ti ààrẹ ní Abuja.

Èrèdí ìpàdé náà kò yẹ ẹnikẹ́ni sùgbọ́n ó seese kó jẹ́ ni ti ọ̀rọ̀ ààbò ìpínlẹ̀ náà nítorí láìpé yi ni ikọ̀lù ibi kan wáyé ní ìjọba ìbílẹ̀ Mangu.

Ìgbà tí ìpàdé náà parí, àwọn oníròyìn béèrè òun tí ìpàdé náà dà lórí lọ́wọ́ Gómìnà Mutfwang, o sì sọ pé ìpàdé náà ti bònkẹ́lẹ́ ni pẹ̀lú ààrẹ, òun kòsí ni leè sọ nǹkan kan nípa rẹ̀.

Ìgbà àkọkọ nìyí tí Gómìnà nìkan náà yóò se ìpàdé bònkẹ́lẹ́ pẹ̀lú ààrẹ lẹ́yìn ìgbà tó ti gùn orí àlééfà ní ọjọ kọkaàdínlọ́gbọ̀n oṣù karùn ún ọdún yìí.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button