Take a fresh look at your lifestyle.

Omituntun 2.0: Makinde Ṣèlérí Ìdàgbàsókè Ọlọ́jọ̀ Pípẹ́ Tí Yòó Tayọ Ìṣèjọba Rẹ̀ Ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

0 141

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde tí ṣèlérí ìdàgbàsókè ọlọ́jọ̀ pípẹ́ ti yóò tayọ ìṣèjọba rẹ, nígbà tí o rawọ ẹbẹ sí gbogbo èèyàn rere Ìpínlẹ̀ náà láti gbárùkù ti ìṣèjọba sáà kejì yìí kò bá lè ṣe àṣeyọrí.

Makinde, ẹni tó fi ìdí tí ètò ààbò fi ṣe pàtàkì nínú ìdàgbàsókè ètò ọrọ ajé ìlú fi ìdí tí o fi gbé ìgbésẹ títú ìgbìmò to n ṣe àkóso Ibùdókọ̀ tẹlẹrí labẹ Alága rẹ Mukaila Lamidi ká, ló sàlàyé pé kò lè sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí akitiyan to ni ìtumọ̀ láì sí ètò ààbò tó péye.

Gómìnà lo sọ ọrọ yìí níbi ètò Ìsìn Idupẹ pàtàkì ní ìrántí Ìṣèjọba eléyìí tí Makinde pé ní ‘Omituntun 2.0′. Ètò to wáyé ní Gbangan Ilé Ìjọsìn St Peters’ to kalẹ sí àgbègbè Aremo ní ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Nínú ọrọ rẹ, Gómìnà fi àsìkò náà sọ di mímọ pé òun fẹ mú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ dé ìpele ìdàgbàsókè ọlọ́jọ́ pipẹ tó bẹẹ tí ìjọba tó bá dé lẹ́yìn òun yóò lè mọ lé orí ìpìlẹ̀ rere tó ti wà nílẹ̀ fún ìlọsíwájú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, nígbà tí o fi dá wọn lójú pé sáà kejì ìṣèjọba òun yóò tún dára ju sáà kínní lọ.

Makinde wá tẹnu mọ pé pàtàkì afojusun ‘Omituntun 2.0’ ni láti jẹ kí ẹnikọọkan ọmọ bíbí àti olùgbé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣe àgbéyẹ̀wò ìgbé ayé wọn nípa yíyàgò fún ọja títà l’ẹba ojú pópó àti fún ìjọba láti pèsè àyíkà tó rọrùn ni ọna àti mú kí o wu oludokowo lati ilẹ òkèèrè láti dá ilé iṣẹ́ sílẹ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Bákan náà, Makinde ẹni tó ká Bíbélì kíkà akọkọ láti inú ìwé Àwọn Ọba Kínní, orí Kẹta, lati ẹsẹ Kínní dé ẹsẹ Ikẹrinla (1Kings 3: 1-14) béèrè pé kí àwọn èèyàn Ọlọrun tẹ síwájú láti máa gbàdúrà fún òun fún èmí ọgbọn àti òye tí yóò fi lè tu ọkọ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ dé èbúté ògo.

Ṣáájú ní Àlùfáà ìjọ náà, Biṣọọbu Àgbà, Ẹni Ọwọ Williams Aladekugbe, nígbà tí o n wàásù lórí àkòrí to pe ní ‘Ohun Ti Bíbélì Sọ Lórí Mẹtalọkan’ jẹ kó di mímọ pé Gómìnà Makinde jẹ àpẹẹrẹ ọmọluwabi to ní ìfẹ ará ìlú lọkan, nígbà tí o tẹnu mọ pé, Gómìnà tí fi hàn pé, ẹni tó nifẹ ará ìlú ní, nípa mímú ìlérí rẹ ṣẹ lásìkò ìṣèjọba sáà akọkọ.

Àlùfáà Aladekugbe wá gbàdúrà kí Ọlọrun fi ẹ̀mí ọgbọ̀n àti òye tí Gómìnà yóò fi tu ọkọ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni sáà kejì yìí dé èbúté ògo jinki rẹ̀.

Lára àwọn tó kọwọ rìn pẹlu Gómìnà ní: Igbakeji rẹ, Bayo Lawal; Aya Gómìnà teleri ní Ìpínlè Ọ̀yọ́, Olóyè Mutiat Ladoja; Onídàájọ Àgbà ni Ìpínlè Ọ̀yọ́, Onídàájọ Iyabo Yerima; àwọn Orí Adé àti Ọrun Ìlẹ̀kẹ̀; ati àwọn èèkàn nínú Ẹgbẹ Òṣèlú PDP jakejado Ìpínlè Ọ̀yọ́

Abiola Olowe
Ìbàdàn.

Leave A Reply

Your email address will not be published.