Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Pàṣẹ Kí Àwọn Ibùdókọ̀ Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Pẹ̀lú Àwọn Adarí Tuntun.

0 163

Ìjọba Ìpínlè Ọ̀yọ́ ti yan Alhaji Tomiwa Omolewa gẹ́gẹ́ bíi Alága Ìgbìmò ti yóò máa ṣe àkóso Ibùdókọ̀ (PMS), nígbà tí o yan Alhaji Kasali Ajisafẹ gẹ́gẹ́ bíi Akọwe.

Bakan náà ní ìjọba tun pàṣẹ kí àwọn Ibùdókọ̀ tí o ti wà ni títì pa fún ìgbà díẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Àwọn Ibùdókọ̀ wọnyii tó ti wa ni títì pa látàrí bi Gómìnà ṣe tu igbimọ to n ṣàkóso tẹ́lẹ̀rí labẹ Alága Mukaila Lamidi ká.

Gẹ́gẹ́ bí atẹjade tí Akọ̀wé ìròyìn fún Gómìnà, Sulaimon Olarewaju ṣe ṣàlàyé, o fi ìdí rẹ múlẹ pé Ìjọba yan àwọn adarí tuntun wọnyii nínú àwọn igun Ẹgbẹ́ Ọlọkọ tó wà jakejado Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Eléyìí wà ní ìbámu pẹ̀lú àbájáde ìpàdé gbàngàn to wáyé ni ọjọ kínní oṣù kẹfà ọdún yìí, níbi tí gbogbo aṣojú igun Ẹgbẹ́ Ọlọkọ kọọkan ti fi ohùn ṣọkan wí pé àwọn yóò gba àlàáfíà láàyè lati ṣiṣẹ́ papọ̀ fún ìlọsíwájú ìgbòkègbódò ọkọ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Bákan náà ní yiyan àwọn adari tuntun wọnyii tún ṣe àfihàn àbájáde ìpàdé gbàngàn náà tó sọ pé kí ìjọba yan adarí láàrin àwọn igun Ẹgbẹ́ Ọlọkọ jakejado Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ki àlàáfíà bá lè jọba.

Yatọ sí Alága àti Akọ̀wé Ìgbìmò ‘PMS’ ti ìjọba ṣẹṣẹ yàn, àwọn ọmọ ìgbìmò yòókù ni, Alhaji Tajudeen Jimoh tíì ṣe Igbákejì Alága (Vice Chairman); Kamarudeen Ìdòwú, Akápò Ẹgbẹ (Treasurer); Tirimisiyu Olowoposi, Akọwe Owó (Financial Secretary); Abass Amolese, Akọwe Ètò Ẹgbẹ (Organizing Secretary); Alhaji Hamidu Mustapha Were, Ayẹwe Owó wò (Auditor).

Àwọn yòókù ní Alhaji Abideen Ejiogbe, Igbakeji Alága Kínní (First Vice Chairman); Ganiyu Mojeed, Turọstii Kínní (First Trustee); Alhaji Alubankudi, Turọstii Kejì ( Second Trustee) ; Alhaji Akinsola Tokyo, Ayẹwe Owó wò Kejì (Second Auditor); àti Wasiu Emiola, Alukoro Ẹgbẹ́ (Public Relations Officer).

Nígbà tí o n sọrọ lẹyin ìkéde ìyànsípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Alága ‘PMS’, Tomiwa Omolewa sọ pé òun yóò ṣiṣẹ láti jẹ kí àlàáfíà jọba ní tìbú-tòòró Ipinlẹ Ọ̀yọ́.

O wá fi àsìkò náà dupẹ lọwọ Gómìnà Seyi Makinde fún bi o ṣe yàn án sí ipò náà, tó sì fi dá àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lójú wí pé iyatọ yóò dé bá bi wọn ṣe n ṣiṣẹ.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave A Reply

Your email address will not be published.