Ìjọba Ìpínlè Ọ̀yọ́ labẹ àkóso Gómìnà Seyi Makinde tí yan Alhaji Oluwatomiwa Omolewa gẹgẹ bíi Alága tuntun fún Ìgbìmò to n ṣàkóso Ibùdókọ̀ (PMS).
Bákan náà ní ìjọba yan Alhaji Kasali Ajisafẹ, ti wọn mọ sí ‘Baba Bola’ gẹgẹ bíi Akọwe ẹgbẹ́.
Eléyìí to jẹyọ nínú atẹjade tí Akọwe Ìròyìn fún Gómìnà, Sulaimon Olarewaju fí síta fún àwọn oníròyìn ní ọjọ Àìkú, ọjọ Kẹrin Oṣù Kẹfà ọdún yìí, nínú èyí tí o ti sàlàyé pé ìyànsípò yìí wáyé ní ìbámu pẹ̀lú àtúntò tí ìjọba tí gùn le nínú ìgbìmò náà.
Ẹ̀kún rẹrẹ ìròyìn náà nbọ lọna.
Abiola Olowe
Ìbàdàn