Àdínkù owó epo ilẹ̀: Ìjọba Nàìjíríà ṣèpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ kátàkár̀a
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ìjọba Nàìjíríà n ṣepade pẹ̀lú àwọn aṣojú ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ kátàkár̀a (TUC), lọ́wọ́ báyìí, ní gbọ̀ngàn ààrẹ, ní Villa, Abuja.
Ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ ní dédé agogo mẹ́rin ìrọ̀lẹ́, yóò dá lórí ìfọ̀rọ̀jomitoro ọ̀rọ̀ fún ìpeniníjà tó ń wáyé nípasẹ̀ yíyọ àdínkù owó epo ilẹ̀.
Àpapọ̀ Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nàìjíríà lápapọ̀ (NLC) àti ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ kátàkár̀a (TUC) ,ṣe ìpàdé pẹ̀lú ìjọba ní Ọjọ́ọ́rú, ṣùgbọ́n wọn kò rí ọ̀rọ̀ náà kò yanjú.
Akọ̀wé fún ìjọba àpapọ̀, George Akume ni ó ṣadarí ikọ̀ ìjọba níbi ìpàdé òní. Àwọn tó kù ni, Gómìnà ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ ti Nàìjíríà (CBN), Godwin Emefie; Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo tẹ́lẹ̀ , Adams Oshiomhole; àti aláṣẹ àgbà àpapọ̀ ti ilé-iṣẹ́ tó ń mójútó epo ilẹ̀ ní Nàìjíríà (NNPCL), Mele Kyari.
Ààrẹ TUC Ọ̀gbẹ́ni Festus Osifo, ni ó ṣadarí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ TUC méje.
Ìròyìn lẹ́kùúnrẹ́rẹ́ nígbà míràn…