Akọrin Ọmọ Orílẹ̀-èdè Naijiria, Tèmíladé Ọpẹ́níyì, ti gba ami ẹ̀yẹ Orin tí wọ́n ń pè ní “Grammy award.”
Tem’s gba àmì ẹ̀yẹ-Melodica Rap Performance tí ó dára jù ní ọjọ́ kẹfà osù Kejì ọdún 2023.
Ó gba àmì ẹ̀yẹ náà torí ipa tí ó kó nínú – Future’s ‘Wait For U’ , tó tún se àfihàn ‘Drake’.
Olùdarí rẹ̀, Muyiwa Awoniyi ló gbé ìròyìn yi jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára instagramu rẹ̀ ní ọjọ́ Ẹtì.
Tems jẹ́ obìnrin Olórin àkọ́kọ́ Nàìjíríà tó kọ́kọ́ gba àmì ẹ̀yẹ irú rẹ̀.
Ó jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tí wọ́n yàn fún àmì ẹ̀yẹ náà. Wọ́n tún yán fún ‘Global Performance category’ tó dára jù ní ọdún tó kọjá fún orin tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jù pẹ̀lú Wizkid ‘Essence’ sùgbọ́n tó pàpà já mọ́ Arooj Aftab ará Pakistan lọ́wọ́.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san