Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ IoD Gba Àwọn Ọ̀gá Àgbà Ilé-isé Ní Ìmọ̀ràn Láti Máa Gbé Ìgbé Ayé Ìlera Pípé

0 171

 

Àjọ Institute of Directors (IoD), ti Nàìjíríà ti rọ àwọn ọ̀gá àgbà Ilé-isé láti máa ṣe Eré ìdárayá bí gbígba bọọlu gọ́ọ̀fù kí wọ́n leè má wà ni ìlera pípé ní ìgbà gbogbo.

Ààrẹ IoD, Dókítà Ije Jidenma, tí Alhaji Tijjani Borodo sojú fún, igbákejì ààrẹ àkọ́kọ́ sọ èyí níbi ayẹyẹ ogójì ọdún ìdíje ere gọ́ọ̀fù ní ìlú Èko

Jidenma sọ pé wíwọ aṣọ ìseré eré gọ́ọ̀fù ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àti àwọn ènìyàn tẹ́wọ́ gbà bí oun tí ó dára àti afẹ́ láwùjọ.

Ọ̀gá àgbà pátápátá ti IoD, Dókítà Dele Alimi, sọ pé wíwọ aṣọ ìseré eré gọ́ọ̀fù máa jẹ kí àwọn ọ̀gá agba láti ní ìfẹ́ sí eré ìdárayá, gbé ìgbé ayé alafia ati pe yóò jẹ kí wọn lọ́wọ́ sí nǹkan míràn yàtọ̀ sí iṣẹ ọ́fíìsì.

Dókítà Godfrey Odijie, Olúborí ìdíje ti gọ́ọ̀fù gbígbá ti IoD sọ pé òun a máa gbá bọ́ọ̀lù gọ́ọ̀fù ni èèmejì ní ọ̀ṣẹ̀, ó sì ní èrè fún òun.
 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button