Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Àjọ FIFA Kí Pinnick Kú Oríire Àmì Ẹ̀yẹ Tí Wọ́n Fún

0 93

 

Ààrẹ Àjọ FIFA, Gianni Infantino, ti kí ọ̀gbẹ́ni Amaju Pinnick, ààrẹ tẹ́lẹ̀ àjọ Nigeria Football Federation kú oríire oyè-Order of the Federal Republic (OFR) tí wọ́n fi da lọ́lá láti ọwọ́ ààrẹ àná Muhammadu Buhari.

Kí Buhari tó lọ ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn ún, ló ti fi oyè dá àwọn ènìyàn bíi Pinnick, Oloye Emeka Anyaoku, Mamman Daura, àti Gómìnà àgbà ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà, Godwin Emefiele, abbl lọ́lá.

Nínú lẹ́tà tí ọ̀gbẹ́ni Infantino kọ, ó sọ pé ògbẹ́ni Pinnick yẹ fún òye náà tó ríi gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ènìyàn rere fún ìtẹ̀síwájú bọ́ọ̀lù ti àjọ FIFA àti ní àgbáyé.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.