Ìbúra: Ìjọba UK kí Ààrẹ Tinubu àti igbákejì rẹ̀ Shettima kú oríire
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ìjọba UK kí Ààrẹ Tinubu àti igbákejì rẹ̀ Shettima kú oríire níbi ayẹyẹ ìbúra fún wọn gẹ́gẹ́ bí́ ààrẹ àti igbákejì orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní sísẹ̀ntẹ̀lé.
Eléyìí wà nínú àlàyé kan tí Aṣojú British sí Nàìjíríà fi síta.
Nínú ìfiránṣẹ́ sí ààrẹ Tinubu, Ọba Aláyélúwà Charles Kẹta tẹnumọ́ ìpinnu rẹ̀ láti mú ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Nàìjíríà nípọn síi.
Ọba náà sọ pé, “Mo kí ẹ kú oríire fún ayẹyẹ ìbúra rẹ gẹ́gẹ́ bí́ ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà,yóò sì jú ọ ṣe ṣe bí o ṣe ń wọṣẹ́ yìí.
“Gẹ́gẹ́ bí a ṣe jọ jẹ́ adarí tó ní àjọṣepọ̀ tó dánmọ́rán,mo lérò pé ìbáṣepọ̀ ààrin àwọn orílẹ̀-èdè wa yóò túnbọ̀ nípọn si lásìkò rẹ.”
Adarí Àwọn Aṣojú UK níbi ìbúra náà ní Abuja ni,Aṣojú Alákòóso káràkátà sí Nàìjíríà,tí ó tún jẹ́ Aṣojú pàtàkì fún ètò Ẹ̀kọ́ àwọn ọmọbìnrin, Helen Grant OBE MP àti Kọmíṣọ́nà British sí Nàìjíríà, Dókítà Richard Montgomery CMG.
Leave a Reply