Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu GCFR, ṣèdárò ikú olùdásílẹ̀ Daar Communications, tí ó ni African Independence Television (AIT) àti Raypower, Olóyè Raymond Dokpesi.
Dokpesi jẹ́pè olúwa ní ọjọ́ Ajé, ní ilé-ị̀wòsàn kan ní Abuja.
Nínú àlàyé kan láti ọ́fíísì rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ajé, ààrẹ ṣàpèjúwe ikú àgbà oníròyìn náà bí ìpàdánù tó lágbára sí ilé-iṣẹ́ ìròyìn àti orílẹ̀-èdè.
“Mo bá àwọn olùṣàkóso àti àwọn òṣìṣẹ́ DAAR Communications àti àwọn ẹbí àgbà akọ̀ròyìn náà kẹ́dùn,” ó sọ báyìí.
Ọmọ rẹ̀ Raymond Dokpesi , ni ó kéde nínú àlàyé rẹ̀ kan pé Alága DAAR Communications jẹ́pè Olúwa ní ọjọ́ Ajé,ọjọ́ kọkàndín-lọ́gbọ̀n,Oṣù Ebìbì,2023.
Wọn bi oloogbe Dokpesi ní ọjọ kẹẹdọgbọn,oṣu Ọwàrà,ní ọdun 1951, ní Ìbàdàn, ipinlẹ Ọyọ, awọn obi rẹ wa lati Agenebode, nipinlẹ Ẹdo.
Leave a Reply