Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí, Jonathan ṣàpèjúwe olóògbé Dokpesi gẹ́gẹ́ bí olùṣòwò aláànú

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 199

Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí, Goodluck Jonathan, ti banújẹ́ lórí ikú olùdásílẹ̀ DAAR Communications, Olóyè àgbà Raymond Dokpesi.

Nínú ìfiránṣẹ́ ìkẹ́dùn kan, Jonathan sọ pé  Nàìjíríà ti pàdánù olólùfẹ́ orílẹ̀-èdè rẹ̀ lódodo àti ẹni tó ní ọkàn tó mọ́.

Jonathan, ẹni tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn abánikẹ́dùn tó kọ́kọ́ ṣàbẹ̀wò sí ilé Dokpesi ní Àbújá, ní ọjọ́ Ajé,ó ní òun bá Dokpesi ṣe ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.

A ó máa ṣèrántí rẹ̀ fún iṣé ọrẹ,ìgbàgbọ́ àti ìṣàkóso tó wúnilórí pàápàá jùlọ olùfilọ́lẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ ìgbohùn sáfẹ́fẹ́ aládàáni, tí ó sí kó ipa pàtàkì nínú ìdàgbàsókè òmìnira àwọn oníròyìn ní Nàìjíríà.,” ó sọ báyìí.

Dókítà Dokpesi di olóògbé ní ọjọ́ Ajé,ní ọmọ ọdún mọ́kànlé-láàdọ́rin.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button