Ayé Dára Dé Ní Ìpínlẹ̀ Katsina: Ìjọba Sèrànlọ́wọ́ Fún Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Jáde Tí Kò Níṣẹ́ lọ́wọ́
Ìjọba Ìpínlẹ̀ Katsina Pẹlu Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ awọn Ijọba Ibilẹ Mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ti o wa ni ipinlẹ naa ti ra àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde ti o din díẹ̀ ni ọ̀ọ́dúnrún lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ohun èlò ètò ọ̀gbìn lójúnà àti pèsè iṣẹ́ fún wọn.
Igbákejì Gomina Ipinlẹ naa, Mannir Yakubu salaye wipe, wọn tun se ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fun awọn tí ó jẹ ànfààní ètò náà lórí lílo àwọn ohun èlò ọ̀gbìn naa.
Gẹ́gẹ́ bi o se sọ, Banki Agbaye ni o se agbátẹrù ètò náà léyìí tí ó sọ àwọn ọ̀tàlélúgba akẹ́kọ̀ọ́ jáde dí àgbẹ̀ ọlọ́kọ́ ńlá. Wọ́n kọ́ nípa ọ̀sìn Ẹja, Adìẹ, Ohun ọ̀gbìn ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ó wá pàrọwà sí àwọn tí ó kópa níbi ètò náà láti lo anfaani naa fun idagbasoke awujọ lápapọ̀.
Leave a Reply