Àwọn Tí Ìdágìrì Lé Kúrò Ní Ibùgbé Wọn Gba Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Lórí Lílo Ẹ̀Rọ Ìgbàlódé Fún Ètò Ọ̀gbìn Ní Ìpínlẹ̀ Anambra
Kò dín ní àádọta ènìyàn nínú àwọn tí ìdágìrì lé kúrò ní ibùgbé wọn ni ó ti kọ́ ìmọ̀ ìgbàlódé nípa lílo àwọn ẹ̀rọ fún ètò ọ̀gbìn lójúnà àti pèsè iṣẹ́ àti oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu
Àjọ kan tí kìí se ti ìjọba ni ó se agbátẹrù ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà, tí wọ́n sì pín ajílẹ̀ fún àwọn tí ó kópa nínú ètò náà
Olùdásílẹ̀ àjọ náà, arábìnrin Ogonna Kanu, sàlàyé wípé ètò náà wáyé láti ran àwọn tí ìdààmú lé kúrò ní àgbègbè wọn lọ́wọ́ fún ètò ọ̀gbìn ọdún yìí. Ó wá gbàwọ́n níyànjú láti má sọ ìrètí nù látàrí ìsòro tí wọ́n dojú kọ, kí wọ́n sì mú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ní òkúkúdùn láti mú ìdàgbàsókè bá ìgbé ayé wọn.
Leave a Reply