Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti gba àwọn àgbẹ̀ nímọ̀ràn láti lo ànfààní àwọn akọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ lórí ìwádìí àti ìdàgbàsókè ètò ọ̀gbìn fún ìdáàbò bo ìkórè oko.
Adarí àgbà àjọ náà, Hussani Ibrahim ni ó fi ìmọ̀ràn náà léde ní ìpínlẹ̀ Sokoto nígbà tí ó ń se ìfilọ́lẹ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé fún ìselọ́jọ̀ Alubọsa àti Ata.
Ó sàlàyé síwájú pé, lópin ìgbà tí a ti ní ẹ̀rọ tí yóò máa se àwọn ìkórè oko wa lọ́jọ̀, ìpèsè oúnjẹ yóò wà lọ́pọ̀ yanturu, ìdènà ebi, àlékún iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ni yóò mú ìgbòòrò bá ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè wa.
Leave a Reply