Àwọn tí ó jẹ ànfààní ohun èlò ọ̀gbìn àti àgbẹ̀ alábominrin ti gbósùbà fún ìsèjọba AbdulRahman AbdulRasaq fún ìgbìyànjú rẹ̀ láti ran àwọn àgbẹ̀ lọ́wọ́ àti láti pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu.
Àwọn àgbẹ̀ náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà nígbà tí alága wọn kówọn sòdí láti se àbẹ̀wò sí oko àgbẹ̀ alábomirin tí ó wà ní Salala, ìlú Afon, ní ìjọba ìbílẹ̀ Asa, ìpínlẹ̀ kwara.
Èyí jẹ́ àfikún sí ìrànlọ́wọ́ tí Gómìnà se fún àwọn àgbẹ̀ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin jádè-jádò ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rìndínlógún tí ó wà ní ìpínlẹ̀ náà àti ètò fún àgbẹ̀ alábominrin tí yóò jẹ́ kí àwọn àgbẹ̀ máa siṣẹ́ yípo ọdún.
Leave a Reply