Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti yan Kamal Abdulgafar Rashed gẹ́gẹ́ bí adarí tuntun fún ilé iṣẹ́ tí ó ń se ìwádìí ìjìlẹ̀ nípa ìlọsíwájú ètò ọ̀gbìn.
Agbẹnusọ àjọ náà, Ọ̀gbẹ́ni Olaifa Taye-Paul ni ó fi ọ̀rọ̀ náà léde.
Mínísítà fún ètò ọ̀gbìn àti ìdàgbàsókè ìgbèríko, Ọmọwe Muhammad Mahmood Abubakar ni ó fi ọwọ́sí ìyànsípò náà.
Ìrètí wà pé adarí tuntun náà yóò lo ọgbọ́n, òye, ìrírí lẹ́nu iṣẹ́ láti darí àjọ náà fún ìdàgbàsókè ètò ọ̀gbìn ní orílẹ̀ èdè Nàíjíríà.
Leave a Reply