Ọba Sulu-Gambari Gbóríyìn Fún Ìjọba Àpapọ̀ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Fún Ìdásílẹ̀ Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ Ẹ̀kọ́ Gírámà
Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà
Emir tí Ìlú Ilorin àti Alága Ìgbìmọ̀ Ọba àti Oyè Ìbílẹ̀ tí Ìpínlẹ̀ Kwara, Alhaji Ibrahim Sulu-Gambari tí gbóríyìn fún Ìjọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún ìdásílẹ̀ Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ètò Ẹ̀kọ́ Ilé-ìwé gírámà tí Orílẹ̀-èdè yìí, (National Secondary School Commission NSSEC).
Gẹ́gẹ́ bí Ọba àkọ́kọ́ ní ìpínlẹ̀ náà, Ìgbìmọ̀ náà pẹ̀lú àgbékalẹ̀ iṣẹ́ wọ́n yóò ràn àwọn ọjẹ̀ wẹ̀wẹ̀ náà lọ́wọ́ lórí ifigagbaga pẹ̀lú àwọn àkẹgbẹ́ wọ́n làgbáyé.
Emir náà sọ pé “Ìgbìmọ̀ náà yóò tún ṣé ìrànwọ́ iṣẹ́ àwọn olùkọ́ àtí àwọn ọmọ ilé-ìwé síwájú sì, pàtàkì jùlọ lórí ìdánwò bíi èdè Gẹẹsi àtí Ìṣirò.”
Alhaji Sulu-Gambari gbóríyìn fún Ìgbìmọ̀ náà fún gígé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọjọ márùn ùn 5 ná wà sí Ilorin, o tẹnumọ pé irú ètò bẹ́ẹ̀ yóò tún mú ìlọsíwájú bá àwọn ọmọ ilé-ìwé àti pàápàá àwọn olùkọ́ látí tún fí kún ẹ̀kọ́ wọ́n.
Tún kà nípa:Aróle Oódua Ọba Adeyeye Ojaja II Ṣé Ìfilọ́lẹ̀ Ẹsìn Adúláwọ̀ Ní Orílẹ̀-èdè Brazil
Alága ìgbìmọ̀ náà, Nimota Akanbi tí sọ fún Emir nípa àwọn ìgbòkègbodò ìgbìmọ̀ náà àti àwọn òun tó tí rí látìgbà tí wọ́n ti dá a sílẹ̀.
O ṣàlàyé pé, pàtàkì jùlọ nínú iṣẹ́ ìgbìmọ̀ náà ní látí ṣé ìlànà tó dára jù fún ètò ẹ̀kọ́ àti látí ṣàkóso ètò ẹ̀kọ́ gírámà àtí láti ṣé atunto ẹ̀ka náà kí òṣuwọn rẹ̀ sí kún bí tí àwọn àkẹgbẹ́ rẹ̀ làgbáyé.
Ambassador Akanbi gbóríyìn fún àwọn ará ìpínlẹ̀ Kwara fún àlejò tí wọ́n àti bí wọ́n ṣé gbá wọ́n láàyè fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà.