Take a fresh look at your lifestyle.

Olórí Ìjọba Alátakò Bèrè Fún Ìdásílẹ̀ Àwọn Ọmọ Ẹgbẹ́ Aṣòfin Ní Orílẹ̀-èdè Kenya

0 246

Olórí Ìjọba Alátakò, Raila Odinga ti bèrè fún idasile àwọn Ọmọ ẹgbẹ́ aṣòfin tí wọ́n kó sí àtìmọ́lé.

Èyí wáyé lẹ́yìn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kan mẹ́rin lára Ọmọ ẹgbẹ́ aṣòfin náà fún ìkórajọ aláìbófin mu tí wọ́n sì kópa nínú ìwọ́de aṣòdì sí ìjọba ní ọjọ́ ajé.

Ọ̀gbẹ́ni Odinga bù ẹnu àtẹ́ lù ìgbésẹ̀ náà pé bí wọ́n se mú wọn jẹ́ ọ̀nà àìtọ́.

Ó ju igba ènìyàn lọ tí wọ́n gbá mú tí wọ́n sì fi sí àtìmọ́lé bí ìròyìn se sọ.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn ọlọ́pàá ju ẹ̀rọ tajútajú sí ọkọ̀ akọ́wọ́rìn ọ̀gbẹ́ni Odinga ní ìlú Nairobi ni àkókò iwode naa.

Ìròyìn ròó pé ìjà bẹ́ sílẹ̀ ní agbègbè Kenyatta Avenue láàrín ọlọ́pàá àtí olùwọ́de tí wọ́n sì ń ju òkúta lu àwọn agbófinró.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.