Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Ti Dájọ́ Pé Ademola Adeleke Ló Jáwé Olúborí Nínú Ìdìbò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Osun lọ́dún 2022.

0 116

Àwọn igun alhaji Adegboyega Oyetola, igun Ademola Adeleke ati, Àwọn àgbẹjọ́rò náà peju si ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó wà nílùú Abuja.

Akọwe ilé ẹjọ́ ka ẹ̀sùn tó wà níwájú ilé ẹjọ́ nípa awuyewuye lórí àbájáde èsì ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni èyí tí ó gbé Ademola Adeleke wọlé gẹ́gẹ́ bi gómìnà ìpínlẹ̀ Òsùn ní ọjọ́ kẹrìndílógún oṣù keje , Ọdún 2022.

Adájọ́ tẹ̀síwájú pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí tó wà níwájú òun, nǹkan kan náà ní àwon ẹ̀rí náà.

Adájọ́ fagilé ẹ̀sùn lórí ẹ̀rọ BVAS, tí wọ́n lo lásìkò ètò ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, pé kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀

Ilé ẹjọ́ fagilé ẹ̀sùn pé Ademola Adélékè sé màgò-mágó ìwé ẹ̀rí tó lò láti fi dìbò.

Ilé ẹjọ́ sọpé gómìnà Ademola Adeleke yege láti díje fún ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun

Ẹjọ́ gbe Adeleke Ademola, adájọ́ ni kí wọ́n ṣàn owó ìtanràn ₦500,000, ẹẹ̀dẹ́gbẹ̀ta ẹgbẹ̀rún náírà Five hundred thousand niara fún Ademola Adeleke

Ilé ẹjọ́ fagilé ẹ̀sùn pé Ademola Adélékè sé màgò-mágó ìwé ẹ̀rí tó lò láti fi dìbò.

Ilé ẹjọ́ sọ pé gómìnà Ademola Adeleke lẹ́ẹ̀tọ́ láti díje fún ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.

Ilé ẹjọ́ fi ẹ̀sùn kan ìgbìmọ̀ tó ń gbọ awuyewuye lórí ètò ìdìbò, ìyẹn Tribunal lórí ìdájọ́ wọn
Ilé ẹjọ́ ní ẹ̀sun tí wón fi kan Ademola Adeleke lórí pé ó sé ayédèrú ìwé ẹ̀rí , kò fẹsẹ̀ múlẹ̀

Lórí ẹ̀sùn pé iye ìbò tí wọ́n dí ju iye àwọn ènìyàn lọ, ìyẹn over voting, ilé ẹjọ́ ní olùfẹ̀sùnkàn kùnà láti mú ẹlẹrìí kankan wá sIlé ẹjọ́ ìgbìmọ̀ tó ń gbọ awuyewuye lórí ètò ìdìbò, ìyẹn Tribunal.

Lẹyin gbogbo atotonu ni ile ẹjọ, Adajọ agba kede Gomina Ademola Adeleke gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo gomina ipinlẹ osun ọdun 2022

Ni bi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ti àwọn akọ̀ròyìn ilé Akéde Nàíjíríà, Voice of Nigeria, Ademola Adepoju ati Akintola George ṣe pẹlu Olóyè Kola Olabisi ti ẹgbẹ oṣelu APC lori ẹjọ Gomina Adeleke ati Oyetola ti wọn gbe wa si ile ẹjọ kotẹmilọrun, o fi ye wa wipe, ko ti tan si ibi yii, awọn ṣi maa de ile ẹjọ giga, iyẹn Supreme Court

Leave A Reply

Your email address will not be published.