Ìjọba Algeria sọ pé ìmọ̀ àwọn kan láti kó àwọn aṣíkiri láti orílẹ̀-èdè Syria lọ sí orílẹ̀-èdè Europe ni àwọn ti bajẹ́.
Afunrasí mẹ́ẹ̀dógún ni wọ́n ti gbámú, mẹ́sàn án jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Syria àti mẹ́fà afunrasí ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Algeria gẹ́gẹ́ bí ìròyìn se sọ.
Eléyìí wá lẹyìn ìwádìí olósù márùn ún kí àṣírí tó tú pé àwọn ènìyàn kan a máa kó àwọn tí kò tọ́ lọ́nà àìtọ́ lọ láti orílẹ̀-èdè Syria àti Lebanoni lọ sí pápákọ̀ òfúrufú tó wà ní ìlà oòrùn Orílẹ̀-èdè Libya, láti ibẹ̀ lọ sínú ọ̀nà aginjù lọ sí etí òkun orílẹ̀-èdè Algeria lọ sí Europe.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san