Èsì ìbò Gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n bí olùkéde ìbò àjọ INEC se kéde fún aráyé gbọ́ àti láti rí.
Èsì Mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nínú Méjìdínlọ́gbọ̀n tí ìbò ti awọn Gómìnà tó wáyé ní ọjọ kejìdínlógún oṣù kẹta ọdún yí ni wọ́n ti kéde rẹ̀.
Ẹgbẹ́ All Progressives Congress, APC borí ní Ìpínlẹ̀ mẹ́ẹ̀dógún, ẹgbẹ́ People’s Democratic Party, PDP borí ní ìpínlẹ̀ mẹ́sàn án, ẹgbẹ́ Labour Party, LP borí ní ìpínlè kan soso (Abia), ẹgbẹ́ New Nigeria Peoples Party (NNPP) borí ní ìpínlẹ̀ kan soso (Kano).
Ìdìbò ni ìpínlẹ̀ Kebbi àti Adamawa ni wọ́n kéde pé kò lópin.
Lákotán, ẹgbẹ́ APC borí ní Ìpínlẹ̀ mẹ́ẹ̀dógún, pẹ̀lú àtúyàn sí ipò àwọn Gómìnà bíi: Babajide Sanwo-Olu (Lagos), Dapo Abiodun (Ogun), AbdulRahman AbdulRazaq (Kwara), Inuwa Yahaya (Gombe), Mai Mala Buni (Yobe), Abdullahi Sule (Nasarawa), Babagana Zulum (Borno).
Ẹgbẹ́ APC ni Gomina ọmọ ẹgbẹ́ tuntun mẹ́jọ sí: Umar Namadi (Jigawa), Ahmed Aliyu (Sokoto), Dikko Radda (Katsina), Uba Sani (Kaduna), Bassey Otu (Cross River), Mohammed Bago (Niger), Hyacinth Alia (Benue), àti Francis Nwifuru (Ebonyi).
Ní ọnà Kejì, ẹgbẹ́ PDP se àseyege ní ìpínlẹ̀ mẹ́sàn án, pẹ̀lú ìyàn sipo padà Gómìnà Seyi Makinde (Oyo) àti Bala Mohammed (Bauchi).
Gómìnà méje tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní abẹ́ àsìá ẹgbẹ́ alátakò náà jẹyọ. Àwọn ni:Peter Mbah (Enugu), Umo Eno (Akwa Ibom), Siminialayi Fubara (Rivers), Kefas Agbu (Taraba), Caleb Mutfwang (Plateau), àti Sheriff Oborevwori (Delta).
Nínú èyí tó fi ìtàn balẹ̀, ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Dauda Lawal gba àga ni ìdí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Zamfara , bẹẹ náà ni ọmọ ẹgbẹ́ APC, Bello Matawalle se.
Ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP, Abba Kabir yẹ̀ àga ni ìdí ọmọ ẹgbẹ́ APC ni ìpínlẹ̀ Kano, bẹẹ náà ni ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, Alex Otti náà se fún ọmọ ẹgbẹ́ PDP ti wọ́n ti ń jẹ ní ìpínlẹ̀ Abia fún ọdún mẹjọ sẹ́yìn.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san