Ààrẹ Nàìjíríà tí wọn ṣẹṣẹ dìbò yàn ti gba àwọn Mùsùlùmí Orílẹ̀-èdè yìí ní Iyànjú ní àkókò ààwẹ̀ Ramadan pé kí wọ́n fi ìwà jọ Prophet Muhammad nínú ìrẹ̀lẹ̀, ìdáríjì, àti iṣẹ́ ìsìn wọn sí ọmọ enìkejì wọn.
Tinúbú gba àwọn Mùsùlùmí ni ìmọ̀ràn láti gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìṣọ̀kan orílè-èdè yìí, kí wọ́n sì ní ìwà rere tí yóò pèsè orílẹ̀-èdè tó dára fún gbogbo ènìyàn.
Ó rọ wọ́n láti gba àdúrà fún àwọn adari wọn ní àkókò ààwẹ̀ àti àdúrà yìí.
Ṣé a kò gbàgbé pé ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Ọ̀gbẹ́ni Tinúbú tẹ ọkọ̀ létí lọ sí Europe láti lọ simi, àti fún lesser hajj, àti fún ìgbáradì ètò ìgbéjọba kalẹ̀ fún alágbádá tí wọn yóò sì búra fún ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kàrùn ún, ọdún 2023.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san