Omiran agbabọọlu awọn obinrin ti ilẹ Afirika, Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà yoo tẹwọgba idije IFE FIFA AWỌN OBINRIN bi ọkọ wọn ti n mu orí lé olu ilu Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà, Abuja ni ọjọ́ Àìkú.
Ife naa ti kuro ni olu ile-iṣẹ FIFA ti o si ti lọ si ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede, yoo si de Naijiria náà, to jẹ ọkan ninu awọn orilẹ-ede meje ti o kopa ninu gbogbo ẹda idije naa, ni irọlẹ Satidee.
Ife naa yoo lọ si gbogbo awọn orilẹ-ede mejilelọgbọn ti o kopa ninu awọn ipari ti ọdun yii, pẹlu ti orílẹ̀-èdè Nàíjíríà yoo jẹ iduro kẹsan-an lori irin-ajo agbaye yii.
Lati igba ti ẹgbẹ agbabọọlu agbaye, FIFA, ti ṣe ifilọlẹ idije asia awọn obinrin ni ọdun kejilelọgbọn sẹyin, Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà, USA, Norway, Germany, Brazil, Japan àti Sweden nikan ni o ti ṣere ni gbogbo ẹda yii.
Gbogbo Orílẹ̀-èdè meje yii ni yoo tun farahan ni bi ipari idije IFE FIFA àwọn obinrin kẹsan-an lati gbalejo wọn nipasẹ Orílẹ̀-èdè Australia àti New Zealand lati ọjọ ogun, oṣu Keje si ogun Oṣu Kẹjọ ọdun yii.