Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde Pè Fún Àdúrà Fún ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Àti Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà Bí Àwọn Mùsùlùmí Lágbayé Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Oṣù Ramadan

0 171

Bi awẹ Ramadan ti ọdún yìí ṣe bẹrẹ, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde bá gbogbo Mùsùlùmí lágbayé yọ bi ojú wọn ṣe rí ibẹrẹ rẹ, tó sì rọ wọn láti lò ànfààní àsìkò náà láti gba ádùrá fún Ipinlẹ Ọ̀yọ́ ati Orilẹ èdè Nàìjíríà àti àwọn adarí rẹ ni gbogbo ẹka ìjọba.

Gómìnà lo sọ ọrọ yìí nínú atẹjade láti ọwọ akọwe ìròyìn fún gómìnà, Taiwo Adisa ninu èyí tíí Gómìnà Seyi Makinde ti gba àwọn Mùsùlùmí níyànjú láti fi gbogbo ọrọ inú Quran mimọ sí ìṣe, nípa ṣíṣe itọrẹ aanu àti ififun ní.

Gómìnà nínú ọrọ rẹ sàlàyé wí pé, oṣù Ramadan je asiko fún ìrùsókè ti ẹmi àti ifọkansin Ọlọhun Allah, nígbà tí o fi kún ọrọ rẹ pé kí àwọn Mùsùlùmí lo anfààní oṣù mímọ yìí láti túbọ̀ múra sí iṣẹ́ ìsìn Allah àti iṣẹ rere sí ọmọ èèyàn.

Makinde nínú ọrọ rẹ sọ pé “Mo kí gbogbo Mùsùlùmí òdodo ni Ìpínlè Ọ̀yọ́ àti àgbáyé fún bi ojú yín ṣe rí oṣù Ramadan ti ọdún yìí. A dupẹ lọwọ Ọlọhun Allah (SWT), ẹni tí o jẹ kí o ṣeéṣe”

O wá fi kún ọrọ rẹ nígbà ti o gba wọn níyànjú láti tẹ síwájú nínú ìṣoore, ififunní, fífi ifẹ hàn sí ara wọn, àti ṣíṣe iranlọwọ fún àwọn aláìní gẹgẹ bíi Òjíṣẹ Muhammad (SWT) ṣe ṣe.

Gómìnà wa gbà adura ki Ọlọhun Allah gbà gbogbo ẹbẹ wọn, kò sí san wọ́n ni ẹsan oloore nínú oṣù ìbùkún yìí.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button